Yoruba Hymn K-Y

Oluwa Iji Fe’soke


Oluwa iji nfe soke Igbi omi nru soke
Oju orun pelu su dudu ‘Ranlowo ko si ntosi
‘Wo ko bere bi a segbe Ba’o niwo se le sun
‘Gbati ‘seju kokan nderu ba wa Pe omi ni’boji wa


Refrain
Afefe at’igbi yo se ‘fe mi.Dake je! Ibase ibinu riru okun
Ibase esu ab’ohunkohun Ko si omi to le ri oko naa
Ti Oluwa orun ati aye wa
Won yoo fi’nu didun se ‘fe mi,Dake je
Won yoo fi’nu didun se ‘fe mi,Dake je


Oluwa pel’ edun emi mi Mo teriba ni ‘ronu
Inu okan mi ko ni ‘sinmi A! Ji ko gba mi,mo be
Igbi ese on ‘binuje Ti b’okan mi mole
Mo segbe,Oluwa,mo segbe A,yara ko si gba mi


Oluwa eru ti koja Idakeje si ti de
Orun f’oju han nin’adagun Orun si wa l’aya mi
Iwo Olurapada mi Ma fi mi sile mo
Pel’ayo ngo d’ebute ibukun Ngo simi l’ebute naa

 


Oluwa, mo gbọ pe Iwọ 


1. Oluwa mo gbọ pe, Iwọ
Nrọ ojo ‘bukun kiri
Itunu fun ọkan arẹ
Rọ ojo na sori mi.
An emi, an’emi
Rọ ojo na sori mi.


2. Ma kọja Baba Olore
Bi ẹsẹ mi tilẹ pọ
Wọ lẹ fi mi silẹ ṣugbọn
Je k’anu Rẹ ba le mi.
An emi, an’emi
Je k’anu Rẹ ba le mi.


3. Ma kọja mi, Olugbala
Jẹ k’emi le rọ mọ ọ
Emi nwa oju rere Rẹ
Pe mi mọ awọn t’o npe.
An emi, an’emi
Pe mi mọ awọn t’o npe.


4. Ma kọja mi, Emi Mimọ
Wọ le la ‘ju afọju
Ẹlẹri itọye Jesu
Sọrọ asẹ na si mi.
Egbe: An emi, an’emi
Sọrọ asẹ na si mi.


5. Moti sun fọnfọn nin’ẹsẹ
Mo bi Ọ ninu kọja
Aiye ti de ọkan mi jo
Tu mi mọ k’o dariji mi.
An emi, an’emi
Tu mi mọ k’o dariji mi.


6. Ife Ọlọrun ti ki yẹ
Ẹjẹ kristi iyebiye
Ore-ọfẹ alainiwọn
Gbe gbogbo rẹ ga n’nu mi.
An emi, an’emi
Gbe gbogbo rẹ ga n’nu mi.


7. Ma kọja, mi dariji mi
Fa mi mọra, Oluwa
“Gba o nf’ibukun f’ẹlomi,
Masai f’ibukun fun mi.
An emi, an’emi
Masai f’ibukun fun mi. Amin

 


Onisegun nla wa nihin


Onisegun nla wa nihin,
Jesu abanidaro;
Oro Re mu ni lara da
A! Gbo ohun ti Jesu!


Refrain:
Iro didun lorin Seraf’,
Oruko idun ni ahon.
Orin to dun julo ni:
Jesu! Jesu! Jesu!


A fi gbogbo ese re ji o,
A! Gbo ohun ti Jesu!
Rin lo sorun lalafia,
Si ba Jesu de ade.


Gbogb’ogo fun Krist’ t’O jinde!
Mo gbagbo nisisiyi;
Mo foruko Olugbala,
Mo fe oruko Jesu.


Oruko Re leru mi lo
Ko si oruko miran;
Bokan mi ti n fe lati gbo
Oruko Re ‘yebiye.


Arakunrin, e ba mi yin,
A! Yin oruko Jesu!
Arabinrin, gbohun soke
A! Yin oruko Jesu!


Omode at’agbalagba,
To fe oruko Jesu,
Le gba ‘pe ‘fe nisisiyi,
Lati sise fun Jesu


Nigba ta ba si de orun,
Ti a ba si ri Jesu,
A o ko ‘rin yite ife ka,
Orin oruko Jesu.