Yoruba Hymn K-Y

Wa ba mi gbe ale fere le tan


1.Wa ba mi gbe, ale fere le tan
Okunkun nsu, Oluwa ba mi gbe;
Bi oluranlowo miran ba ye
Iranwo alaini, wa ba mi gbe.


2. Mo nfe O ri, ni wakati gbogbo
Kilo le segun esu b’ore Re?
Tal’o le se amona mi bi Re?
N’nu ‘banuje at’ayo ba mi gbe.


3. Wa ba mi gbe, ni wakati iku,
Se ‘mole mi, si toka si orun
B’aye ti nkoja, k’ile orun mo
Ni yiye, ni kiku, wa ba mi gbe.

 


Wa Sodo Jesu


1. Wa sodo Jesu, mase duro,
L’oro Re l’O ti f’ona han wa,
O duro Ni Arin wa loni,
O nwi jeje pe, “Wa.”


Refrain
Ipade wa yio je ayo,
Gba okan wa ba bo lowo ese,
T’a o si wa pelu Re, Jesu,
Ni ile wa lailai.


2. “Je k’omode wa,” A! gbohun Re!
Je k’okan gbogbo ho fun ayo;
Ki asi yan Oun l’ayanfe wa;
Ma duro, sugbon wa.


3. Tun ro, O wa pelu wa loni,
F’eti s’ofin Re, k’o si gboran,
Gbo b’ohun Re ti n wi pele pe,
“Eyin omo Mi wa!”

 


Wa, Eyin Olooto


Wa eyin olooto, Layo at’ isegun,
Wa ka lo, wa ka lo si Betlehem,
Wa ka lo wo o! Oba awon Angeli.


Egbe
E wa ka lo juba Re,
Ewa ka lo juba Re,
E wa ka lo juba
Kriti Oluwa.


Olodumare ni, Imole ododo,
Kosi korira inu Wundia;
Olorun paapaa ni, Ti a bi, ti a ko da.


Angeli e korin, Korin itoye re;
Ki gbogbo eda orun si gberin:
Ogo f’Olorun Li oke orun.


Ni tooto, a wole, F’Oba t’a bi loni;
Jesu iwo l’a wa nfi ogo fun:
’Wo omo Baba, To gba’ra wa wo.