Yoruba Hymn K-Y

Ki N Mo Nipa Jesu Sii


Mo fe mo nipa Jesu sii,
F’or’ ofe Re h’ elomiran;
Ki n le ri ‘gbala kikun Re,
Ki n mo ‘fe ‘ni to ku fun mi.


Egbe:
Ki n mo nipa Jesu sii,
Ki n mo nipa Jesu sii;
Ki n le ri ‘gbala kikun Re,
Ki n mo ‘fe ‘ni to ku fun mi


N o ko nipa Jesu sii,
Ki n da ‘fe Re mimo mo si i;
K’ Em’ Olorun j’oluko mi,
Fi ona ti Kristi han mi.


Ki n mo Jesu si n’oro Re,
Ki n ma b’Oluwa mi soro;
Ki n si gbo ‘ro Re lokokan,
So ‘ro ‘tito Re di t’emi.


Ki n mo Jesu l ‘ori ‘te Re,
Pel’ oro gbogbo Ogo Re;
Mo bi’joba Re ti n po si,
Bibo Re Oba ‘lafia

 


Ki nfe o si Kristi


1.Ki nfe o si Kristi
Ki nfe o si
Gb adura ti mo ngba
L or ekun mi
Eyi ni ebe mi


Refrain
Ki nfe o si kristi
Ki nfe o si
Ki nfe o si


2.L ekan ohun aye
Ni mo ntoro
Nisiyi wo nikan
Ni emi nwa
Eyi l adura mi


3. Je ki banuje de
At irora
Didun l o jise re
At ise won
Gba won mba mi k orin


4. Nje opin emi mi
Y o jiyin re
Eyi y o je oro
Ikehin mi
Adura mi y o je

 


Ko Su Wa Lati Ma Ko Orin ti Igbani


1.Ko su wa lati ma ko orin ti igbani Ogo f’olorun Aleluya
A le fi igbagbo korin na s’oke kikan Ogo f’olorun, Aleluya!


Refrain:
Omo olorun ni eto lati ma bu s’ayo Pe ona yi nye wa si,
Okan wa ns’aferi Re Nigb’o se a o de afin Oba wa ologo,
Ogo f’olorun, Aleluya!


2. Awa mbe n’nu ibu ife t’o ra wa pada, ogo f’olorun Aleluya!
Awa y’o fi iye goke lo s’oke orun Ogo f’olorun, Aleluya!


3. Awa nlo si afin kan ti a fi wura ko, ogo f’olorun Aleluya!
Nibiti a ori Oba ogo n’nu ewa Re Ogo f’olorun, Aleluya!


4. Nibe ao korin titun t’anu t’o da wa nde Ogo f’olorun Aleluya!
Nibe awon ayanfe yo korin ‚yin ti Krist; Ogo f’olorun, Aleluya