Yoruba Hymn K-Y

Mo ntesi waju Lona Na


Mo n te siwaju lona na
Mo n goke si lojojumo
Mo n gbadura bi mo ti n lo
Oluwa jo gbe mi soke


Refrain:
Oluwa jo gbe mi soke
Fami lo si ibi giga
Apata to ga jumi lo
Oluwa jo gbe mi soke


Ife okan mi ko duro
Larin ‘yemeji at’eru
Awon miran le ma gbe’be
Ibi giga lokan mi fe


Mo fe ki nga ju aye lo
Ninu ogo didan julo
Mo ngbadura ki nle de ‘be
Oluwa mumi de ‘le na.


Fa mi lo si ibi giga
L’aisi Re nko ni le de ‘be
Fa mi titi d’oke orun
Ki nkorin lat’ibi giga.

 


Mo ti ni jesu lore


VERSE 1
Mo ti ni Jesu l’ore, yebiye l’o je fun mi,
On nikan l’arewa ti okan mi fe,
On ni itanna ipado, Ninu re ni ri,
Iwenumo ati imularada ;
Olutunu mi l’oje, Ninu gbogbo wahala
On ni ki nko eru mi l’on lori


Refrain
On ni Itanna Ipado Irawo Owuro
On nikan l’arewa ti okan mi fe


VERSE 2
Mo ko edun mi to wa, gbogbo banuje mi,
gba danwo, on l’odi agbara mi.
mo n’itelorun n’nu re, mo k’orisa sile,
Yio si fi agbara re dabobo mi,
Aiye le ko mi sile , esu le tan mi je,
Nipa Jesu ngo de’le ireri,


VERSE 3
On ki yio fi mi sile, ko si je tan mi nu,
Ife re le’mi yio se titi dofin;
BI mo wa l’afonifoji,emi ki yio beru,
On je Orun ni yio fi bo okan mi
Gba ba ngbade ogo,emi yio roju re
Nibiti omi iye nsan titi lai,

 


Mo Ti Seleri Jesu


1. Mo ti seleri Jesu,
Lati sin O dopin;
Ma wa lodo mi titi,
Baba mi Ore mi.
Emi k’yo beru ogun,
B’Iwo ba sun mo mi,
Emi ki y’o si sina,
B’O ba fona han mi.


2. Je ki n mo p’O sunmo mi,
’Tori’baje aiye;
Aiye fe gba okan mi,
Aiye fe tan mi je,
Ota yi mi ka,kiri,
Lode ati ninu;
Sugbon Jesu, sunmo mi,
Dabobo okan mi.


3. Je ki emi k’ o ma gbo,
Ohun Re, Jesu mi,
Ninu igbi aiye yi,
Titi nigbagbogbo.
So k’ o f’ okan mi bale,
Teri okan mi ba;
So k’ emi le gbo Tire,
’Wo Olutoju mi.


4. ’Wo ti se ’leri Jesu,
F’awon t’ o tele O,
Pe ibikibi t’O wa,
Lawon yio si wa;
Mo ti se ’leri Jesu,
Lati sin O dopin.
Je ki n ma to O lehin,
Baba mi, Ore mi.


5. Je ki n ma ri ’pase Re,
Ki n le ma tele O;
Agbara Re nikan ni,
Ti m’ ba le tele O:
To mi, pe mi, si fa mi
Di mi mu de opin,
Si gba mi si odo Re,
Baba mi, Ore mi.