Gbati mori agbelebu
1. Gbati mo ri agbelebu
Ti a kan Oba Ogo mo
Mo ka gbogbo oro s’ofo
Mo kegan gbogbo ogo mi.
2. K’a mase gbo pe mo nhale
B’o ye n’iku Oluwa mi
Gbogbo nkan asan ti mo fe
Mo da sile fun eje Re
3. Wo, lat’ ori, owo, ese
B’ikanu at’ ife ti nsan;
‘Banuje at’ ife papo,
A fegun se ade ogo
4. Gbogbo aye ‘baje t’emi.
Ebun abere ni fun mi;
Ife nla ti nyanilenu
Gba gbogbo okan, emi mi.Amin.
Gbo Aye Gbe Jesu Ga
1. Gbogbo aye, gbe Jesu ga
Angeli ewole fun
Emu ade oba re wa
Se l’oba awon oba
2. Ese loba eyin martyr
Ti npe ni pepe re
Gbe gbongbo igi, jesse ga
Se l’oba awon oba
3. Eyin irun omo Israeli
Ti a ti rapada
Eki eni t’o gba yin la,
Se l’oba awon oba
4. Gbogbo eniyan elese
Ranti banuje yin
Ete ‘kogun yin sese re
Se l’oba awon oba
5. Ki gbogbo orile ede
Ni gbogbo agbaye
Ki won ki, “kabiyesile
Se l’oba awon oba
6. A bale pe l’awon t’orun
Lati ma juba re
K’a bale jo jumo korin
Se l’oba awon oba
Gbo Eda Orun Nkorin
1. Gbo eda orun nkorin,
“Ogo fun Oba t’ a bi.”
“Alafia l’ aiye yi,”
Olorun ba wa laja,
Gbogbo eda, nde l’ ayo,
Dapo mo hiho t’ orun;
W’ Alade Alafia!
Wo Orun ododo de.
Ref
Gbo eda orun nkorin
Gbo fun Oba t’ a bi.
2. O bo ‘go Re s’ apakan,
A bi, k’ enia ma ku,
A bi, k’ O gb’ enia ro,
A bi, k’ O le tun wa bi.
Wa Ireti enia,
Se ile Re ninu wa;
Nde, Iru Omobirin
Bori Esu ninu wa;
3. Pa aworan Adam run,
F’ aworan Re s’ ipo re;
Jo, masai f’ Emi Re kun
Okan gbogb’ onigbagbo.
Ogo fun Oba t’ a bi
Je ki gbogbo wa gberin.
“Alafia l’ aiye yi,
Olorun ba wa laja.