Yoruba Hymn A-J

Etun won ko fun mi ki ngbo


Etun Won Ko Fun Mi Ki N Gbo
Oro ‘yanu t’ Iye!
Je ki nsi tun ewa won ri,
Oro ‘yanu t’ Iye,
Oro iye at’ ewa, ti mko mi n’ igbagbo!


Refrain:
Oro didun! Oro ‘yanu
Oro didun! Oro ‘yanu
Oro ‘yanu t’ Iye.
Oro ‘yanu t’ Iye.


Kristi nikan lo fi fun ni
Oro ‘yanu t’ Iye!
Elese gbo ‘pe ife na
Oro ‘yanu t’ Iye,
L’ ofe la fifun wa, ko le to wa s’orun


Gbo ohun ihinrere na,
Oro ‘yanu t’ Iye!
F’ igbala lo gbogbo enia
Oro ‘yanu t’ Iye,
Jesu Olugbala, we wa mo titi lai!

 


Fa mi mora


Tire lemi se, mo ti gbohun Re
O nso ife Re si mi.
Sugbon mo fe n’de lapa igbagbo,
Ki nle tubo sunmo O


Refrain:
Fa mi mora, mora, Oluwa
Sib’agbelebu t’O ku
Fa mi mora, mora, mora Oluwa
Sib’eje Re to niye


Ya mi si mimo fun ise Tire,
Nipa ore-ofe Re:
Je ki n fi okan igbagbo woke,
Kife mi te siTire.


A! Ayo mimo ti wakati kan
Ti mo lo nib’ite Re;
‘Gba mo gbadura si Olorun mi,
Mo ba soro bi ore,


Ijinle ife nbe ti ko le mo
Titi n o koja odo
Ayo giga ti emi ko le so
Titi n o fi wa simi,

 


Fi ibukun Re tu wa ka


1.Fi ibukun Re tu wa ka,
Fi ayo kun okan wa;
K’olukuluku mo ‘fe Re
K’a l’ayo n’nu ore Re;
Tu wa lara tu wa l’ara
La aginju aye ja.


2. Ope at’ iyin l’a nfun O
Fun ihinrere ayo;
Je ki eso igbala Re,
Po l’okan at’iwa wa;
Ki oju Re, ki oju Re
Ma ba wa gbe titi lo


3. Nje n’igbat’ a ba si pe wa
Lati f’aye yi sile
K’Angeli gbe wa lo s’orun,
L’ayo ni k’a j’ ipe na;
K’a si joba, k’a si joba
Pelu Kristi titi lae.Amin.