Yoruba Hymn A-J

Jesu ‘wọ ni t’emi laelae


Jesu ‘wọ ni t’emi laelae O ju Gbogbo Ọrẹ lọ.
Ni Gbogbo irin- ajo mi, A! Mba le faramọ Ọ
Sunmọ Ọ, Sunmọ Ọ, Sunmọ Ọ, Sunmọ Ọ,
Ni Gbogbo irin- ajo mi, A! Mba le faramọ Ọ


K’i ṣe fun ọrọ aye yi, Ni mo ṣe ngbadura yi;
Tayọtayọ ni uno jiya, Bi mba sa le Sunmọ Ọ
Sunmọ Ọ, Sunmọ Ọ, Sunmọ Ọ, Sunmọ Ọ,
Tayọtayọ ni uno jiya, Bi mba sa le Sunmọ Ọ.


‘Gbat’ ajo mi ba dopi Mu mi gunlẹ sọdọ Rẹ,
ṣi ilẹkun ayeaye Ki nsunmọ Ọ titi lae;
Sunmọ Ọ, Sunmọ Ọ, Sunmọ Ọ, Sunmọ Ọ,
ṣi ilẹkun ayeaye Ki nsunmọ Ọ titi lae.

https://youtu.be/5EdIQVkKH-0

 


Jesu yo joba ni gbogbo


1. Jesu yo joba ni gbogbo
Ibit’ aba le ri orun:
‘Joba Re yo tan kakiri,
‘Joba Re ki o nipekun.


2. On li ao ma gbadura si,
Awon oba yo pe l’Oba;
Oruko Re b’orun didun
Y’o ba ebo oro g’oke.


3. Gbogbo oniruru ede,
Yo fi ‘fe Re korin didun;
Awon omode yo jewo,
Pe ‘bukun won t’odo Re wa.


4. ‘Bukun po nibi t’On joba,
A tu awon onde sile,
Awon alare ri ‘simi,
Alaini si ri ‘bukun gba.


5. Ki gbogbo eda ko dide,
Ki won f’ola fun Oba wa;
K’angel’ tun wa t’awon t’orin
Ki gbogb’ aye jumo gberin.
Amin.