Yoruba Hymn A-J

Gba Jesu ba de lati pin ere


Gba Jesu ba de lati pin ere,
B’ o j’ osan tabi l’ oru,
Y’o ha ba wa nibit’ a gbe ns’ ona,
Pel’ atupa wa tin tan?


Refrain:
A le wipe a mura tan ara,
Lati lo s’ ile didan?
Yio ha ba wa nibit’ a gbe ns’ ona?
Duro, tit’ Oluwa yio fi de?


Bi l’ owuro, ni afemojumo
Ni Yi o pe wa l’ okankan;
Gbat’ a f’ Oluwa l’ ebun wa pada,
Yio ha dahun pe, “O seun?”


A s’ oto ninu ilana Re,
Ti sa ipa wa gbogbo?
Bi okan wa ko ba da wa l’ ebi,
A o n’ isimi ogo.


Ibukun ni fun awon ti ns’ ona,
Nwon o pin nin’ ogo Re.
Bi O ba de l’ osan tabi l’ oru,
Yio ha ba wa n’ isona?

 


Gbat’alafia b’odo nsan s’ona mi


Gbat’alafia b’odo nsan s’ona mi
Ti banuje bo okan mi
Ninu ‘pokipo O nko mi ki nwipe
O dara o dara f’okan mi


Egbe
O dara(O dara) f’okan mi(f’okan mi)
O dara o dara f’okan mi


Bi Satani dide ti idanwo si de
Je ki bukun yi s’akoso
Pe Krist ka ‘po aini ranlowo mi si
O ti ta eje Re f’okan mi


Ese mi, ero ogo to mu mi yo
Ese mi gbogbo lo gbe lo
O kan m’agbelebu Re nko ni ru no
Yin Jesu yin Jesu okan mi


Oluwa jek’ere igbagbo mi sa de
K’awosanma kuro b’aso
T’ipe ba si dun t’Oluwa sokale
Be na ni o dara f’okan mi

 


Gbati ipe Oluwa ba dun


Gbati ipe Oluwa ba dun
T’akoko ba si pin
T’imole owuro mimo n tan lailai;
Gbat’awon ta ti gbala
Yo pejo soke odo naa,
Gba ta n pe oruko lohun, n o wa nbe.


Refrain
Gba ta n pe oruko lohun
Gba ta n pe oruko lohun
Gba ta n pe oruko lohun
Gba ta n pe oruko lohun
N o wa nbe.


Looro daradara tawon
Oku mimo y’o dide
Togo ajinde Jesu o je tiwon
Gba t’awon ayanfe Re yo
Pejo nile lok’orun,
Gba ta n pe oruko lohun, n o wa nbe.


Je ka sise f’Oluwa
Latowuro titi dale
Ka soro ‘fe yanu ati’toju Re;
Gbat aye ba dopin tise
Wa Si pari nihin,
Gba ta n pe oruko lohun, n o wa nbe.