Yoruba Hymn A-J

E yo ninu Oluwa


Ẹ yọ nínú Oluwa ẹ yọ,
Ẹyin t’ọkan rẹ ṣe dede;
Ẹyin t’o ti Yan Oluwa,
Le ‘banujẹ at’aro lọ.


Refrain:
Ẹ yọ! Ẹ yọ!
Ẹ yọ nínú Oluwa ẹ yọ!
Ẹ yọ! Ẹ yọ
Ẹ yọ nínú Oluwa ẹ yọ!


Ẹ yọ tori On l’ Oluwa,
L’ayé ati l’ọrun pẹlu;
Ọrọ Rẹ bor’ohun gbogbo,
O l’agbara lati gbala.


‘Gbat’ ẹ ba nja ija rere,
Ti ọta fẹrẹ bori yin;
Ogun Ọlọrun t’ẹ ko ri
Pọ jù awọn ọta yin lọ.


B’okunkun tilẹ yi ọ ka,
Pẹlu iṣudẹdẹ gbogbo
Maṣe jẹ k’ọkan rẹ danu,
Sa gbẹkẹl’Oluwa, d’opin.


Ẹ yọ nínú Oluwa ẹ yọ,
Ẹ kọrin iyin Rẹ kikan;
Fi duru ati ohun kọ
Aleluya l’ohun goro’.

 


Emi ’Ba N’ Egberun Ahon(Lydia)


1. E mi ‘ba n’egberun ahon,
Fun ‘yin Olugbala
Ogo Olorun Oba mi
Isegun Ore Re.


2. Jesu t’o seru wa d’ayo
T’o mu banuje tan
Orin ni l’eti elese
Iye at’ilera.


3. O segun agbara ese
O da onde sile
Eje Re le w’eleri mo
Eje Re seun fun mi


4. O soro, oku gb’ohun Re
O gba emi titun ;
Onirobinujeje y’ayo
Otosi si gbagbo


5. Odi, e korin iyin re
Aditi , gbohun Re
Afoju, Olugbala de,
Ayaro, fo f’ayo


6. Baba mi at’olorun mi,
Fun mi ni ‘ranwo Re
Kin le ro ka gbogbo aiye
Ola oruko Re. Amin.

 


Enikan mbẹ to fẹràn wa


Verse 1
Enikan mbẹ to fẹràn wa
A! O fẹ wa
Ìfẹ Rẹ ju ti yekan lọ
A! O fẹ wa
Ọrẹ aiye nkọ wa sile
B’oni dun ọla le koro
Ṣugbọn ọrẹ yi ko ntan ni
A! O fẹ wa


Verse 2
Iye ni fún wa bí a bá mọ
A! O fẹ wa
Ro b’a ti jẹ n’igbese to
A! O fẹ wa
Ẹjẹ Rẹ l’O si fi ra wa
Nin’aginju l’O wa wa ri
O sí mu wa wa Sagbo Rẹ
A! O fẹ wa


Verse 3
Ọrẹ ododo ni Jesu
A! O fẹ wa
O fẹ lati maa bukun wa
A! O fẹ wa
Ọkan wa fẹ gbọ Ohùn Rẹ
Ọkan wa fẹ lati sunmọ
On nako sí ni tan wa jẹ
A! O fẹ wa


Verse 4
L’okọ Rẹ l’a nri dariji
A! O fẹ wa
On le ọta wa sí ẹyin
A! O fẹ wa
On o pese ‘bukun fun wa
Ire l’a o ma ri titi
On o fi mú wa lọ s’ogo
A! O fẹ wa. Amin