Yoruba Hymn A-J

Bi Krist’ ti da okan mi n’de


1. Bi Krist’ ti da okan mi n’de
Aiye mi ti dabi orun
Larin’banuje at’aro
Ayo ni lati mo Jesu


Egbe
Halleluya! ayo l‘oje
Pemo ti ri dariji gba
Ibikibi ti mo ba wa
Ko s‘ewu Jesu wa nibe


2. Mo ti nrope orun jinna
Sugbon nigbati Jesu de
L’orun ti de’ nu okan mi
Nibe ni y’o si wa titi


3. Nibo la ko le gbe l’aiye?
Lor’oke tabi petele
L’ahere tabi agbala
Ko s’ewu Jesu wa nibe

 


Bi mo tiri Lais’ awawi


1. Bi mo ti ri, lai s’awawi
Sugbon nitori eje Re
B’o si ti pe mi pe ki nwa
Olugbala, mo de.


2. Bi mo ti ri, laiduro pe
Mo fe k ‘okan mi mo toto
S’odo Re to le we mi mo
Olugbala, mo de.


3. Bi mo ti ri, b’o tile je
Ija l’ode, ija ninu
Eru l’ode, eru ninu
Olugbala, mo de.


4. Bi mo ti ri, osi are
Mo si nwa imularada
Iwo le s’awotan mi
Olugbala, mo de.


5. Bi mo ti ri ‘wo o gba mi
‘wo o gba mi, t’owo t’ese
‘tori mo gba ‘leri Re gbo
Olugbala, mo de.


6. Bi mo ti ri ife Tire
L’o sete mi patapata
Mo di Tire, Tire nikan
Olugbala, mo de.


7. Bi mo ti ri, n’nu ‘fe nla ni
T’o fi titobi Re han mi
Nihin yi ati ni oke
Olugbala, mo de. Amin.

 


Bo ti dun lati gba Jesu


Bo ti dun lati gba Jesu
Gbo gege bi oro Re
Ka simi lor’ileri Re
Sa gbagbo l’Oluwa wi


Chorus
Jesu, Jesu, emi gbagbo
Mo gbekele ngbagbogbo
Jesu, Jesu, Alabukun
Ki nle gbekele O si


Bo ti dun lati gba Jesu
Ka gbeje wenumo
Re Igbagbo ni ki a fi bo
Sin’eje ‘wenumo na


Bo ti dun lati gba Jesu
Ki nk’ara ese sile
Ki ngb’ayo, iye, isimi
Lati odo Jesu mi


Mo yo mo gb’eke mi le
O Jesu mi, Alabukun
Mo mo pe o wa pelu mi
‘N’toju mi titi d’opin.

https://youtu.be/FH29XBqrQ9Y