Ayo B’aiye! Oluwa De
Ayo b’aiye! Oluwa de;
K’aiye gba Oba re;
Ki gbogbo okan mura de,
K’aiye korin soke K’aiye korin soke
K’aiye, K’aiye korin soke.
Ayo b’aiye! Jesu joba,
E je ‘ka ho f’ayo;
Gbogbo igbe, omi, oke,
Nwon ngberin ayo na, Nwon ngberin ayo na,
Nwon ngberin, Nwon ngberin ayo na.
K’ese on ‘yonu pin laiye,
K’egun ye hun n’ile;
O de lati mu ‘bukun san,
De’bi t’egun gbe de, De’bi t’egun gbe de
De’bi t’egun, De’bi t’egun gbe de.
O f’ oto at‘ ife joba,
O jek’ Oril’ ede
Mo, ododo Ljoba Re,
At’ife ‘iyanu Re, At’ife ‘iyanu Re,
At’ife , at’ife ‘iyanu Re.
B’ Oruko Jesu Ti Dun To(Tune: St Peter)
1. B’oruko Jesu ti dun to,
L’eti olugbagbo!
O tan ‘banuje on ogbe,
O le eru re lo.
2. O mu ogbe emi re tan
O mu aiya bale:
Manna ni fun okan ebi,
Isimi f’ alare.
3. Apata ti mo kole le
Ibi isadi mi
Ile isura mi t’o kun
F’opo ore-ofe.
4. Jesu, Oko mi, Ore mi,
Woli mi, Oba mi
Alufa mi, Ona, Iye
Gba orin iyin mi.
5. Ailera L’agbara ‘nu mi,
Tutu si L’ ero mi,
‘Gba mo ba ri O b’ O ti ri,
Ngo yin O b’ o ti ye;
6. Tit’ igbana ni ohun mi
Y’ o ma robin ‘fe Re;
Nigba iku k’ oruko Re.
F’ itura f’ okan mi.
Baba wa Ti n be Lorun
Baba wa ti’n be l’orun
K’a bowo f’oruko reKi ijoba re de
K’a she ‘fe re ‘laiye
B’ won ti’n se l’orun o!
Fun wa l’ounje ti ojo oni
Dari ese ji waB’awa n’se dariji
Ma fa wa si nu idanwoGba wa nu bilisi
T’ori ‘joba ni ti ire
Ati agbara, Ogo ni t’ ire
Titi l’aiyeAmin.