Yoruba Hymn A-J

Gbogb’ogo iyin, ola


Chrous:
Gbogb’ ogo iyin ola
Fun O, Oludande,
S’ Eni t’ awon omode
Ko Hosanna didun!


1. ‘Wo l’ Oba Israeli,
Om’ Alade Dafidi,
T’ O wa l’ Oko Oluwa,
Oba olubukun.


2. Egbe awon maleka,
Nyin O l’ oke giga;
Awa at’ eda gbogbo
Si dapo gberin na.


3. Awon Hebru lo, saju,
Pelu imo ope,
Iyin, adura, at’ orin,
L’ a mu wa ‘waju Re.


4. Si O, saju iya Re,
Nwon korin iyin won;
‘Wo t’a gbega nisiyi,
L’ a nkorin iyin si.


5. ‘Wo gba orin iyin won:
Gb’ adura t’a mu wa,
‘Wo ti nyo s’ ohun rere,
Oba wa Olore.

 


Idapo didun ti nfunni l’ayo


1. Idapo didun ti nfunni l’ayo
Mo ngbekele Jesu Oluwa
Ifaiyabale at’itelorun
F’awon to ngbekele Oluwa


Egbe
Mo ngbekele
Ko s’ewu biti Jesu wa
Mo ngbekele
Mo ngbekele Jesu Oluwa


2. A! b’o ti dun to lati ma rin lo
Mo ngbekele Jesu Oluwa
Ona na nye mi si lojojumo
Mo ngbekele Jesu Oluwa


3. Ko si ‘beru mo ko si ‘foiya mo
Mo ngbekele Jesu Oluwa
Okan mi bale pe mo ni Jesu
Mo ngbekele Jesu Oluwa.

 


Igbagbo mi duro lori


Igbagbo mi duro lori
Eje atododo Jesu
N’ko je gbekele ohun kan
Leyin oruko nla Jesu


Refrain
Mo duro le Krist’ apata
Ile miran, iyanrin ni
Ile miran, iyanrin ni


B’ire ije mi tile gun
Ore-ofe Re ko yi pada
Bo ti wu k’iji na le to
Idakoro mi ko ni ye


Majemu ati eje Re
L’emi o ro mo b’ikunmi de
Gbati ohun aye bo tan
O je ireti nla fun mi


Gbat’ipe kehin ba si dun
A! m ba le wa lodo Jesu
Ki nwo ododo Re nikan
Ki n duro niwaju ite