Yoruba Hymn A-J

A fope f’Olorun lokan ati Lohun Wa


A fope f’Olorun lokan ati lohun wa:
Eni sohun ‘yanu, n’nu Eni taraye n yo.
Gba ta wa lomo’wo, Oun na lo n toju wa,
O si febun ife se’toju wa sibe.


Oba Onibuore, ma fi wa sile lailai,
Ayo ti ko lopin oun ‘bukun yoo je tiwa.
Pa wa mo ninu ore, to wa ‘gba ba damu,
Yo wa ninu ibi laye ati lorun.


Ka fiyin oun ope f’Olorun Baba, Omo
Ati Emi Mimo ti O ga julo lorun
Olorun kan lailai taye atorun n bo
Bee l’O wa d’isinyi, beeni y’O wa lailai.

 


Aajin Jin, Oru Mimo


Aajin jin, oru mimo,
Ookun su, mole de,
Awon Olus’aguntan n sona,
Omo titun to wa loju orun,
Sinmi n’nu alafia
Sinmi n’nu alafia.


Aajin jin, oru mimo,
Mole de, ookun sa,
Oluso aguntan gborin Angel’,
Kabiyesi aleluya Oba.
Jesu Olugbala de
Jesu Olugbala de.


Aajin jin, oru mimo,
‘Rawo orun tan mole
Wo awon Amoye ila orun
Mu ore won wa fun Oba wa,
Jesu Olugbala de
Jesu Olugbala de.


Aajin jin, oru mimo,
‘Rawo orun tan ‘mole
Ka pelu awon Angel korin,
Kabiyesi aleluya Oba
Jesu Olugbala de
Jesu Olugbala de.

 


Agbara n be n’nu eje Jesu


1. Agbara mbe n‘nu eje Jesu,
‘Tori o w‘ese mi nu;
Mo si mo pe isin Re li ayo,
O s‘okun mi di ‘mole.


Ref
Agbara mbe, agbara t‘o sise ‘yanu
Agbara mbe; agbara ti o nwe wa mo
Mbe ninu eje Jesu. (Amin)


2. Agbara mbe n‘nu eje Jesu
O gba mi LOWO ebi,
‘Gbati mo k‘eru ese mi to wa
Eje Re si we mi mo.


3. Emi mo ire t‘eje na nje,
O ti so wa di titun
Nipa eje Re iyebiye na,
Mo di mimo titi lae.