Mo f’ ara mi fun o
1. Mo f’ ara mi fun o
Mo ku nitori re,
Ki nle ra o pada,
K’ o le jinde nn’ oku;
M’ f’ ara mi fun O,
Kini ‘wo se fun Mi.
2. Mo f’ ojo aiye Mi
Se wahala fun o;
Ki iwo ba le mo
Adun aiyeraiye;
Mo lo opo ‘dun fun o,
O lo kan fun mi bi?
3. Ile ti Baba Mi,
At’ ite ogo Mi;
Mo fi sile w’ aiye;
Mo d’ alarinkiri:
Mo f’ile tori re,
Ki l’o f’ile fun Mi?
4. Mo jiya po fun o,
Ti enu ko le so;
Mo jijakadi nla,
‘Tori igbala re;
Mo jiya po fun O,
O le jiya fun Mi?
5. Mo mu igbala nla,
Lat’ ile Baba Mi
Wa, lati fi fun o;
Ati idariji;
Mo m’ ebun wa fun O,
Kil ‘o mu wa fun Mi.
6. Fi ara re fun Mi,
Fi aiye re sin Mi;
Diju si nkan t’aiye,
Si wo ohun t’ orun;
Mo f’ ara Mi fun O,
Si f’ ara re fun mi O.
Amin.
Mo f’aye at’ife mi fun
Mo f’aye at’ife mi fun
Od’aguntan to ku fun mi;
Je ki n le je olotito,
Jesu Olorun mi.
Refrain:
N o wa f’Eni t’O ku fun mi,
Aye mi yo si dun pupo;
N o wa f’Eni to ku fun mi,
Jesu Olorun mi.
Mo gbagbo pe Iwo n gbani
‘Tori ‘Wo ku k’emi le la;
Emi yo si gbekele O,
Jesu Olorun mi.
Iwo t’O ku ni Kalfari,
Lati so mi dominira;
Mo yara mi soto fun O,
Jesu Olorun mi.
Mo fe O n’gbagbogbo
Mo fe O n’gbagbogbo,
Oluwa Olore
Ko s’ ohun ti nfun ni
L’ alafia bi Tire.
Refrain:
Mo fe O, a! mo fe O,
Ni wakati gbogbo;
Bukun mi Olugbala,
Mo wa s’ odo Re.
Mo fe O n’ gbagbogbo,
Duro ti mi,
Idanwo ko n’ ipa
Gbat’ O wa nitosi.
Mo fe O n’ gbagbogbo,
L’ ayo tab’ irora;
Yara wa ba mi gbe,
K’ aiye mi ma j’ asan.
Mo fe O n’gbagbogbo,
Ko mi ni ife Re;
K’ O je k’ileri Re
Se si mi li ara.
Mo fe O n’gbagbogbo,
Ologo julo;
Se mi n’ Tire toto,
Omo alabukun.