Yoruba Hymn K-Y

Korin t‘ife ‘yanu Jesu


1. Korin t‘ife ‘yanu Jesu,
Anu at‘ or‘-ofe Re;
Yio pese ayo fun wa
N‘ile Baba Re loke.


EGBE:
‘Gba ta ba d‘orun rere,
Bawo li ayo wa yo ti po to!
Gba ta ba ri Jesu,
Ao yo, ao korin isegun.


2. B‘a ti nrin lo l‘on‘ ajo wa,
Okun yo su l‘ona wa,
Laipe oru ekun yo di
Owuro orin ayo


3. E je ka ma foriti lo,
Ka ma sin tokantokan;
Ta ba ri ninu ogo Re,
Ao gbagbe iponju wa.


4. Tesiwaju, ere daju;
Laipe ao ri ewa Re;
Ao silekun ita wura
N‘biti ao ma gbe titi.

https://youtu.be/Fy5RTnpvf-Y

 


Krist’ Oluwa ji loni


Krist’ Oluwa ji loni, – Halleluyah,
Eda at’ Angeli nwi – Halleluyah.
Gb’ ayo at’ isegun ga – Halleluyah.
K’ orun at’ aiye gberin! – Halleluyah.


O tun wa, Oba ogo: – Halleluyah.
“Iku itani re wa?” – Halleluyah.
Lekan l’ O ku k’ O gba wa, – Halleluyah.
“‘Boji, isegun re wa?” – Halleluyah.


Ise ti idande tan; – Halleluyah.
O jija, O ti segun; – Halleluyah.
Wo, ‘ponju orun koja – Halleluyah.
Ko wo sinu eje mo – Halleluyah.


E je k’ awa goke lo, – Halleluyah.
Sodo Kristi Ori wa, – Halleluyah.
A sa jinde pelu Re, – Halleluyah.
Bi a ti ku pelu Re. – Halleluyah.


Oluwa t’ aiye t’ orun, – Halleluyah.
Tire ni gbogbo iyin, – Halleluyah.
A wole niwaju Re – Halleluyah.
‘Wo Ajinde at’ Iye. – Halleluyah.

 


Loroke leyin ilu


1. Lor’oke lehin ‘lu, l’agbelebu kan wa
Apẹrẹ iya at’ egan
Ọkan mi fa sibe, s’Olufẹ mi ọwọn
T’a pa f’ẹsẹ gbogbo aiye.


Refrain:
Un o gbe agbelebu Rẹ naa ru
Titi un o fi de ibi ere
Emi o rọmọ agbelebu naa,
K’emi le de ade nikẹhin


2. Lor’ agbelebu yi, ti araiye kẹgàn
On l’o si lẹwa loju mi,
Nitori’ Ọm’Ọlọrun, bọ ogo Rẹ silẹ
O si ti ru u lo si Kalfari


3. L’ar’ agbelebu yi, l’eje mimo san si,
O lewa pupo loju mi
Toripe lori re, Jesu jiya fun mi
O f’ese ji, o we mi mo


4. Emi y’o j’olootọ, S’enit’o ku fun mi,
Un o yo s’ẹgan at’ ‘tiju
Nigbooṣe y’o pe mi lọ ‘le aiyeraiye,
Ki nle pin ninu ogo Rẹ