Yoruba Hymn K-Y

Olutunu ti de


1. Tan ihin na kale, jakejado aye,
K’awon ti eru npa, mo pe igbala de:
K’awon ti se ti Krist’, so ihin ayo na,
Olutunu ti de.


Refrain:
Olutunu ti de, Olutunu ti de,
Emi lat’ oke wa, ileri Baba wa;
Tan ihin na kale, jakejado aye,
Olutunu ti de.


2. Oba awon oba, wa f’iwosan fun wa,
O wa ja ide wa, O mu igbala wa,
K’olukuluku wa, korin isegun pe:
Olutunu ti de.


3. Ife iyanu nla, a! mba le royin na,
Fun gbogbo eniyan, ebun or’ofe Re;
Emi omo egbe, di omo igbala,
Olutunu ti de.


4. Gbe orin ‘yin soke, s’Olurapada wa,
K’awon mimo loke, jumo ba wa gberin
Yin ife Re titi, ife ti ko le ku,
Olutunu ti de.

 


Oluwa Iji Fe’soke


Oluwa iji nfe soke Igbi omi nru soke
Oju orun pelu su dudu ‘Ranlowo ko si ntosi
‘Wo ko bere bi a segbe Ba’o niwo se le sun
‘Gbati ‘seju kokan nderu ba wa Pe omi ni’boji wa


Refrain
Afefe at’igbi yo se ‘fe mi.Dake je! Ibase ibinu riru okun
Ibase esu ab’ohunkohun Ko si omi to le ri oko naa
Ti Oluwa orun ati aye wa
Won yoo fi’nu didun se ‘fe mi,Dake je
Won yoo fi’nu didun se ‘fe mi,Dake je


Oluwa pel’ edun emi mi Mo teriba ni ‘ronu
Inu okan mi ko ni ‘sinmi A! Ji ko gba mi,mo be
Igbi ese on ‘binuje Ti b’okan mi mole
Mo segbe,Oluwa,mo segbe A,yara ko si gba mi


Oluwa eru ti koja Idakeje si ti de
Orun f’oju han nin’adagun Orun si wa l’aya mi
Iwo Olurapada mi Ma fi mi sile mo
Pel’ayo ngo d’ebute ibukun Ngo simi l’ebute naa

 


Oluwa ni Oba


1. Oluwa ni Oba,
E bo Oluwa nyin,
Eni kiku, sope,
Y’ayo ‘segun titi,


Ref(1-3)
Gb’okan at’ohun nyin soke
“E yo” mo si tun wi, “E yo”


2. Olugbala joba,
Olorun otito,
“Gbat’ O we ‘se wa nu
O g’oke lo joko,


3. O mbe l’odo Baba
Titi gbogbo ota
Yio teri won ba
Nipa ase Tire,


4. Yo n’ireti ogo
Onidajo mbo wa,
Lati mu ‘ranse Re
Lo ‘le aiyeraye.
A fe gbo ‘hun angel nla na,
Ipe y’o dun wipe, “E yo “ Amin.