Are mu o, okan re poruru
Are mu O, okan re poruru?
So o fun Jesu, So o fun Jesu
Ibanuje dipo ayo fun o?
So o fun Jesu nikan.
Refrain
So o fun Jesu; so o fun Jesu
Oun lore ti yoo mo
Ko tun sore
Ati’yekan bi Re
So o fun Jesu nikan
Asun-dakun omije lo nsun bi?
So o fun Jesu, so o fun Jesu,
O l’ese to farasin f’eniyan
So o fun Jesu nikan
‘Banuje teri okan re ba bi?
So o fun Jesu, so o fun Jesu
O ha nsaniyan ojo ola bi?
So o fun Jesu nikan
Ironu iku mu o damu bi?
So o fun Jesu, so o fun Jesu
Okan re nfe ijoba Jesu bi!
So o fun Jesu nikan
Ati gbo iro didun
1.Ati gbo iro didun, Jesu le gbanila,
Ji ‘se na yi aiye ka, Jesu le gbanila,
K’e so fun gbogbo aye Gun oke, koja okun,
Oluwa pase k’e lo Jesu le gbanila.
2.E soo lori ’ji okun, Jesu le gbanila;
Wi fun gbogbo elese, Jesu le gbanila,
Ekọrin, erekusu Gberin na, eyin okun,
Ki gbogbo aiye ma yo, Jesu le gbanila.
3. Kọrin naa soke kikan, Jesu le gbanila,
lku at’ajinde Re, L’o ti fi gbanila,
Kọrin ’jee n’gba ’banuje, Gbat’okan wa nfe anu,
Kọrin ’ṣẹgun lor’iku, Jesu le gbanila.
4. Afefe gbohun soke, Jesu le gbanila,
Gbogboril’ede, eyo, Jesu le gbanila,
Kede igbala ofe, Si gbogb’orile aye,
Orin iṣẹgun wa ni, Jesu le gbanila.
Awe o ninu ẹjẹ Ọdaguntan
O ti tọ Jesu F’agbara ‘Wẹnumọ
A wẹ ọ ninu ẹjẹ Ọdaguntan
Iwọ ha ngbẹkẹle ore-ọfẹ Rẹ?
A wẹ ọ ninu ẹjẹ Ọdaguntan
Refrain
A wẹ ọ, ninu ẹjẹ,
Ninu ẹjẹ Ọdaguntan fún ọkàn;
Aṣọ rẹ y’o fúnfún y’o sí mo laulau
A wẹ ọ ninu ẹjẹ Ọdaguntan
O mba Olugbala rin lojojumo?
A wẹ o ninu ẹjẹ Ọdaguntan?
O simile ẹnití a kan mọ igi
A wẹ ọ ninu ẹjẹ Ọdaguntan
Aṣọ rẹ funfun lati pad’ Olúwa?
O mọ lau ninu ẹjẹ Ọdaguntan?
ọkàn rẹ mura fún ‘le didan lókè?
Ka wẹ ọ ninu ẹjẹ Ọdaguntan