Yoruba Hymn A-J

Alẹ Mimọ


Alẹ Mimọ awon irawo ti wa ni didan
Oje oru ojo ibi olugbala wa
Asi gun bimkpe ni ese ati aside
Titi ofi han ti Okàn si ro ire
Inu didun ireti aye ti o sanyo
Agbati ofi ope si titun o logo owuro
Subu Lori èkun re
Gbo ohun Awon Angeli
Alẹ Ibawi
Alẹ Oru nigbati a bi Kristi
Alẹ Alẹ Mimọ
Alẹ Alẹ Mimọ

 


Alejo kan ma nkankun


1. Alejo kan ma nkankun,
Pe E wole
O ti npara ‘be tip e
Pe E wole.
Pe wole ki o to lo,
Pe wole, Eni Mimo,
Jesu Krist’ Omo Baba,
Pe E wole!


2. Silekun okan re fun u
Pe E wole;
B’o ba pe y’o pada lo,
Pe E wole!
Pe wole ore re ni
Y’o dabobo okan re
Y’o pa o mo de opin,
Pe E wole.


3. O ko ha ngbo ohun Re?
Pe E wole;
Se l’ore, re nisiyi
Pe E wole!
O nduro l’ enu ‘lekun,
Yio fun o l’ ayo,
‘Wo o yin oruko Re,
Pe E wole!


4. P’ alejo Orun wole
Pe E wole!
Yio se ase fun o,
Pe E wole!
Y’o dari ese ji o,
Gbat’ o ba f’aiye sile
Y’o mu o de ‘le Orun
Pe E wole.

 


Apata Ayeraye


Apata ayeraye
Se ibi isadi mi;
Je ki omi oun eje,
T’o n san lati iha Re,
Se iwosan f’ese mi,
K’o si so mi di mimo.


K’ Ise ise owo mi,
Lo le mu ofin Re se;
B’ itara mi ko l’are,
T’ omije mi n san titi;
Won ko to fun etutu,
‘Wo nikan l’o le gbala.


Ko s’ohun ti mo mu wa,
Mo ro mo agbelebu;
Mo wa, k’o d’aso bo mi,
Mo n wo o fun iranwo;
Mo wa sib’ orisun ni,
We mi, Olugbala mi.


‘Gbati emi mi ba n lo,
T’iku ba p’oju mi de,
Ti mba n lo s’aye aimo,
Ti n ri o n’ite ‘dajo;
Apata ayeraye,
Se ibi isadi mi.