Yoruba Hymn A-J

Jesu Fe Mi


1. Jesu fe mi emi mo,
Bibeli so fun mi bee,
Tire l’awon omode,
Won ko l’agbara, Oun ni.


Refrain
A! Jesu fe mi,
A! Jesu fe mi,
A! Jesu fe mi,
Bibeli so fun mi.


2. Jesu fe mi, O ti ku
Lati si orun sile;
Yi o we ese mi nu,
Y’o je komo Re wole


3. Jesu fe mi, O fe mi,
Bi emi tile saisan,
Lor’akete arun mi,
O t’ite Re wa so mi.


4. Jesu fe mi yi o duro,
Timi lona mi gbogbo,
O’n pese aaye fun mi,
Lojo kan n o r’oju Re.

 


Jesu nikan li a nwasu


1. Jesu nikan li a nwasu
Jesu nikan l’a nrohin
Awa y’o gbe Jesu soke
On nikan l’awa nfe ri


Ref
Jesu nikan, Jesu nikan
Jesu nikan l’orin wa
Olugbala, Oluwosan
Oba ti mbo lekeji (Amin)


2. Jesu ni Olugbala wa
O ru gbogbo ebi wa
Ododo Re lo gbe wo wa
O ns’agbara wa d’otun


3. Jesu l’o nso wa di mimo
T’o nwe abawon wa nu
O nsegun ese at’ ara
Nipa iranwo Emi


4. Jesu ni Oluwosan wa
O ti ru ailera wa
Nip’ agbara ajinde Re
A ni ilera pipe


5. Jesu nikan l’agbara wa
Agbara Pentokosti
Jo, da agbara yi lu wa
F’Emi Mimo Re kun wa


6. Jesu ni awa nduro de
A nreti ohun ipe
‘Gbat’O ba de, Jesu nikan
Y’o je Orin wa titi

 


Jesu olufe okan mi


Jesu, olufẹ ọkàn mi, jẹ ki nsala s’aiya re,
Sa t’irumi sunmo mi, sa ti ji nfe s’oke
Pa mi mo Olugbala, tit’ iji aiyey’o pin,
To mi lo s’ebute re, nikehin gba okan mi.


Abo mi, emi ko ni, Iwọ lokan mi ro mo,
Ma f’emi nikan sile, gba mi, si tu mi ninu,
Iwọ ni mo gbekele, Iwọ n’iranlowo mi;
Masai f’iye apa re, D’abo b’ori aibo mi.


Kristi, ‘wo nikan ni mo fẹ, n’inu rẹ mo r’ohun gbogbo
Gb’ eni t’o subu dide, w’alaisan, at’ afọju.
Ododo l’oruko re, alaiododo l’emi
Mo kun fun ese pupo, Iwọ kun fun Ododo.


’Wo l’opo ore ọfẹ, lati fi bor’ ese mi,
Jẹki omi Iwọsan, We inu ọkàn mi mo,
Iwọ l’orisun iye, jẹ ki mbu n’nu re l’ofe
Ru jade n’nu okan mi, Si iye ainipekun.