Tan ihin na kale, jakejado aye
1. Tan ihin na kale, jakejado aye,
K’awon ti eru npa, mo pe igbala de:
K’awon ti se ti Krist’, so ihin ayo na,
Olutunu ti de.
Ref
Olutunu ti de, Olutunu ti de,
Emi lat’ oke wa, ileri Baba wa;
Tan ihin na kale, jakejado aye,
Olutunu ti de. (Amin.)
2. Oba awon oba, wa f’iwosan fun wa,
O wa ja ide wa, O mu igbala wa,
K’olukuluku wa, korin isegun pe:
Olutunu ti de.
3. Ife iyanu nla, a! mba le royin na,
Fun gbogbo eniyan, ebun or’ofe Re;
Emi omo egbe, di omo igbala,
Olutunu ti de
4. Gbe orin ‘yin soke, s’Olurapada wa,
K’awon mimo loke, jumo ba wa gberin
Yin ife Re titi, ife ti ko le ku,
Olutunu ti de.
Tan ‘mole
Ipe na ndun l’otun ati l’osi pe
Tan ‘mole, Tan ‘mole
Opo l’o nku laini ireti orun
Tan ‘mole, Tan ‘mole.
Ref
Tan ‘mole, ‘mole ihinrere
Je k’o tan yi aye ka
Tan ‘mole, ‘mole ihinrere
Je k’o tan yi aye ka.
Ati gbo ipe Makidonia loni
Tan ‘mole, Tan ‘mole
Mu won wa jeje s’ibi agbelebu
Tan ‘mole, Tan ‘mole.
Je k’agbadura k’or’ofe le joba
Tan ‘mole, Tan ‘mole
Ki Emi Krist’ joba ni lbi gbogbo
Tan ‘mole, Tan ‘mole.
Ki amase kaare ni’se ife na,
Tan ‘mole, Tan ‘mole
Je ka sise kale gbade nikehin,
Tan ‘mole, Tan ‘mole.
Tun muwa soji
1. A yin O ‘lorun, nitor’ Omo ‘fe Re,
Fun Jesu ti o ku to si lo soke
Refrain
Halleluya, tire logo
Halleluya, Amin;
Halleluya, tire logo,
Tun mu wa soji.
2. A yin O ‘lorun, f’ emi ‘mole Re,
To f’ Olugbala han To mu ‘mole wa.
3. Ogo ati ‘yin f’ odagutan ta pa,
To ru gbogb’ ese wa to w’ eri wa nu.
4. Sa mu wa soji, f’ ife Re k’ okan wa;
K’ okan gbogbo gbina fun ina orun.