Yoruba Hymn K-Y

Ojo Ibukun Yio si ro


Ojo Ibukun yo si ro Eyi n’ileri ife
A o ni itura didun; Lat‘ odo OLugbala


Ref:
Ojo Ibukun, Ojo Ibukun l’a nfe
Iri anu to yi wa ka,
Sugbon Ojo l’a ntoro (Amin)


Ojo Ibukun y’o si ro Isoji iyebiye
Lori oke on petele Iro opo ojo mbo


Ojo Ibukun y’o si ro Ran won si wa Oluwa
Fun wa ni itura didun; Wa, f’ola fun oro Re


Ojo Ibukun y’o si ro Nwon ‘ba je le wa loni
B’a ti njewo f’Olorun wa T’a npe oruko Jesu

 


Ojonla Lojo Na


Ojo nla l’ojo ti mo yan Olugbala l’ Olorun mi
O ye ki okan mi ma yo K’o si ro ihin na ka le.


Refrain Ojo nla l’ojo na, Ti Jesu we ese mi nu
O ko mi ki nma gbadura Ki nma sora, ki nsi ma yo
Ojo nla l’ojo na, Ti Jesu we ese mi nu.


Eje mimo yi ni mo je F’ enit’ o ye lati feran
Je k’orin didun kun ‘le Re Nigba mo ba nlo sin nibe.


Ise igbala pari na Mo di t’Oluwa mi loni
On l’o pe mi ti mo si je Mo f’ ayo jipe mimo na.


Simi, aiduro okan mi Simi le Jesu Oluwa
Tani je wipe aiye dun Ju odo awon Angeli?


Enyin orun, gbo eje mi Eje mi ni ojojumo
Em’ o ma so dotun titi Jesu y’o fi mu mi re ‘le.

 


Ọkan mi yin Ọba ọrun


Ọkan mi yin Ọba ọrun Mu ọrẹ wa sọdọ Rẹ;
‘Wọ ta wosan, t’ a dariji, Tal’ aba ha yin bi Rẹ?
Yin Oluwa, Yin Oluwa, Yin Ọba ainipẹkun.


Yin, fun anu t’ o ti fi han, F’ awọn Baba ‘nu pọnju;
Yin I Ọkan na ni titi, O lọra lati binu,
Yin Oluwa, Yin Oluwa, Ologo n’ nu otitọ.


Bi baba ni O ntọju wa, O si mọ ailera wa;
Jẹjẹ l’ o ngbe wa lapa Rẹ, Ogba wa lọwọ ọta,
Yin Oluwa, Yin Oluwa, Anu Rẹ, yi aye ka.


Angel’, ẹ jumọ ba wa bọ, Eyin nri lojukoju,
Orun, Oṣupa, ẹ wol Ati gbogbo agbaye,
E ba wa yin,E ba wa yin, Ọlọrun Olotitọ.

or


Ọkan mi yin Ọba ọrùn
Mu ọrẹ wa s’ọdọ Rẹ
‘Wọ t’a wosan t’a dariji
Ta laba ha yin bi Rẹ
Yin Oluwa yin Oluwa
Yin Ọba àìnípẹkun.


Yin fún anu t’O ti fihan
F’awọn Baba ‘nu pọnju
Yin l’ọkan na ni titi
Ọlọra lati binu
Yin Oluwa, yin Oluwa,
Ologo n’nu òtítọ.


Bi baba ni O ntọjú wa,
O si mọ ailera wa
Jẹjẹ l’o ngbe wa l’apa Rẹ,
O gba wa lọwọ ọta,
Yin Oluwa, yin Oluwa,
Anu Rẹ yi aiye ka.


A ngba b’itana eweko
T’afẹfẹ nfẹ t’ o si nrọ
‘Gbati a nwa, ti a sì nku,
Ọlọrun wa bakanna,
Yin Oluwa, yin Oluwa
Ọba alainipẹkun.


Angẹl, ẹ jumọ ba wa bọ,
Ẹnyin nri lojukoju
Orun osupa ẹ wolẹ,
Ati gbogbo agbaiye
Ẹba wa yin, Ẹba wa yin
Ọlọrun Olotitọ. Amin

https://youtu.be/QpElh7lEhzE